Saturday, November 17, 2018

Aro Dida (Yoruba Dye Making)


Awon ohun elo fun aro dida niyi: Omi-aluba, eeru soso-eyin, opolopo omi, ikoko arimole, ikoko kekeeke meji, opa-aro, aso funfun, elu, opon ti o fe ti eniyan le te aso le.

Ise obinrin ni ise yii bee si ni "aredu" je ikini fun awon alaro. Ise alaro ni ki o fi aro bu ewa kun aso nipa rire e sinu aro. Die lara awon ilu ti aro dida ti wopo ni Ibadan, Oyo, Osogbo, Iseyin, Iwo, Ijebu, ati Abeokuta.

Aroko Asapejuwe (Ebi Ogbeni Ajayi)


Oruko mi ni Ade Ajayi bee ni mo si je omodekunrin lati ile adulawo, Afirika. Mo n gbe pelu baba mi, iya mi, awon aburo mi lokunrin ati lobinrin. Iyaaya mi ati iya-baba mi n gbe pelu wa bakan naa. Lai fa oro gun, ebi Ogbeni Ajayi ko ju bayii lo.

A n gbe ninu ile ti baba mi ko. Eyi wa ni okan lara awon ileto ti eniyan le ba pade ni Iwo-Oorun Afirika.

Tuesday, November 13, 2018

Orin Etiyeri (Yoruba Musical Satire)


Awon eya Yoruba ti a n pe ni Oyo ni o ni orin etiyeri. Ipa ti orin efe n ko ni Egbado ni orin etiyeri paapaa n ko laarin awon ara Oyo.

Ewi amuludun ni etiyeri n se. Won maa n lo o lati fi parowa awon iwa ibaje ti o n sele lawujo. Nitori pe orin ni, o maa n mu lile ati gbigbe lowo.

Orin etiyeri naa tun wa fun idanilekoo, idanilaraya ati ipanilerin-in tori pe awon oro apara ati awon oro alunfansa maa n tawotase ninu ewi alohun naa.

Ko tan sibe, a tun maa n fi orin eriyeri se iwure.

Awon odomokunrin bi marun-un tabi ju bee ni maa n kora jo korin etiyeri kaakiri adugbo.

Ni aye atijo, onkorin etiyeri maa n wo aso bi egungun sugbon eyi ko ri bee mo lode oni.

Apeere:
Lile:- E maa pe yoo se
Egbe:- A a se
Lile:- Ode roko, ode peran
Egbe:- A a se
Lile:- Eran ki lode pa?
Egbe:- A a se
Lile:- Ode peran okete
Egbe:- A a se
Lile:- Iku a re wa kete
Egbe:- A a se
Lile:- Arun a re wa kete
Egbe:- A a se...

Fun Ekunrere Eko, E Lo Si www.olukoni.blogspot.com

Saturday, November 3, 2018

Gbolohun Onibo VS Awe-gbolohun Afibo


Akiyesi ti fi han gbangba pe awon akekoo maa n gbe alaye oro mejeeji yii funra won. Eyi lo fa a ti a fi pinnu pe ki a to toka si ohun ti o mu gbolohun onibo yato si awe-gbolohun afibo, a oo koko ran a leti oriki gbolohun ati awe-gbolohun.

Ki ni gbolohun? Gholohun ni akojopo oro ti a n lo lati fi gbe ero okan jade ni ibamu pelu ofin isowo-lo-ede. Orisirisi ona ni a le gba pin gbolohun ede Yoruba nipa fifi oju ihun, ilo, tabi iye oro-ise wo o.

Awon ounje Nile Yoruba (Yoruba Indigenous Cuisine)Okan lara ohun ti o n toka asa ni ounje. Bi a se ni awon ounje ti a le pe ni ti gbogoogbo bee naa ni a ni eyi tii se ti awon Yoruba ponmbele. Kannpa ni ounje fun gbogbo omo adarihurun, eyi lo si fa a ti a fi ni orisirisi owe ajemo ounje nile Yoruba. Owe kan so pe ohun ti eye ba je ni eye n gbe rorun.

Wiwa laaye ati laye eniyan ro mo ounje ti eniyan ba n je. Awon ounje afunni lokun wa, bee naa ni awon ounje amaradan naa wa pelu, eyi lo mu awon Yoruba maa so wi pe ounje lore awo.

Tuesday, October 9, 2018

Iro Ohun ati Ami Ohun (Yoruba Tonal Sounds and Signs)


Iro Ohun ni ilana igbesoke gbesodo ohun eniyan ti o n se ifo. A le pin iro ohun si meji ninu ede Yoruba; iro ohun geere (iro ohun oke, iro ohun isale ati iro ohun aarin) ati iro ohun eleyoo (iro ohun eleyooroke ati iro ohun eleyoorodo).

Friday, September 28, 2018

Ogun Jija Laye Atijo (Yoruba Ancient War)

Image from Google Search


  • Ohun ti o n fa ogun jija: Lara awon ohun ti o maa n mu ki ogun jija be sile lawujo Yoruba, laye atijo, ni a ti ri egun agbara awon alagbara, aala ile, ife lati konileru, ati bee lo.
  • Ipalemo ogun: Oba alaafin lo ni ase lati sigun si ilu miiran. Ki won to se eyi, won yoo bi ifa leere boya isigun oun ko ni ba ewu de. Leyin eyi ni awon eso omo-ogun yoo gbera lo soju ogun.
  • Awon omo ogun: Nile Yoruba, Oye ti oba ma fi n da akoni jajunjagun lola ni oye Aare Ona Kakanfo. Amo ti a ba n soro nigba orisirisi ipo awon omo ogun laye atijo nile Yoruba (Ancient Yoruba Military Ranks), Balogun ni ipo ti o ga ju. Balogun naa ni awon isomogbe tire. Seriki ni ipo ti o tele ti Balogun nigba ti Asiwaju je ipo ti o kangun si ipo Seriki. Leyin eyi ni Sarumi (awon omo-ogun ti o maa n fi esin ja).
  • Eto ogun jija: Ni owoowo ni won maa n to ja ogun ni oju-ogun (battle field) ni aye atijo. Awon to wa niwaju ni yoo koko sigun tira won ki awon ti o tele won to woya ija loju-ogun.
  • Ami: Ni awon omo-ogun ti n sise ajemotelemuye. Awon ni a n pe ni (spy) in ede Geesi. Won a mura bi ajeji lasan wo inu ilu ti won fe kogun ja lati fi ogbon mo ipalemo de ogun ti n bo lona.
  • Odi: Eyi ni ogiri giga ti a ko yi ilu po ki o le soro fun ilu miiran lati kogun ja ilu naa.
  • Yara: Eyi ni koto ti a wa yi odi-ilu ka ki o ma ba rorun fun ilu miiran lati kogun ja ilu naa.
  • Alore: Eyi ni awon omo-ogun ti o n so ibode ilu. Won a si ta ara ilu ni olobo bi won ba keefin ijamba tabi ikolu to n bo lona.


ARTICLES YOU MUST READ

    ---