Dishing Out Yoruba The Best Way (warning: do not translate with software to avoid misinterpretation)

Asayan Ewi Alohun Fun Itupale

No comments :

Ewi alohun ni awon ewi abalaye awa Yoruba ti ogun logbon – on si ni ewi alohun. Die lara won ni

(1) Ese ifa: Eyi ni litireso ti oro mo Ifa ti a tun mo si orunmila. Awon olusin ifa ati awon babalawo lo maa ki ese ifa. Awon oro to maa n waye ninu ese ifa ni “Adie fun”, “kee pe tee jina” “Ebo riru” “Ijo ni n jo” “ayo ni n yo” lara awon ohun elo ifa dida ni ikin, opele, ibo, iroote, opon ifa, agere tabi awon ifa, apo ifa, ilu ifa.
Ori buruku kii wu tunle
A ki da ese asiwere mo lona
A kii mo ori oloye awujo
A dia fun moloowu
Tii se obinrin ogun
Ori ti yoo joba lola
Enikan ko mo on
Ki tiko taya yee peraa won
Wi were mo.

(2) Ijala: Eyi je mo ogun ati awon olusin re. iru ewi yii si maa n waye nibi ayeye bi isomoloruko, isile, odun ogun, igbeyawo, oye jije. Ikini, onti owe pipa, iwure lo maa n wa ninu ewi yii.

(3) Iwi tabi esa egungun: eyi je mo awon egungun. Yoruba gbagbo wi pe ara orun ni egungun bee ohun ti egungun ba wo bi aso no won pe ni eku. Egungun oni dan ni o n pesa, awon oje ati awon obinrin idile eleegun maa n kiwi tabi pesa. Lara ohun to maa n waye ninu ewi ewi yii ni iba, oriki, itan, orin, ijo ntori wipe awon egungun feran lati maa jo.
Oba kee pe mo juba kiba mi se
Iba ni n o ko ju na, are mi deyin
Mo juba baba mi………
Oje larinnaka, oko iyadunni
Omu leegun alare, a – bi – koko – leti aso.

(4) Ekun iyawo: Eji je mo igbeyawo. Aarin awon oyo ni ekun iyawo ti wopo. Nitori ifoya ti o maa n waye fun obinrin ti yoo fi ile obi re sile lo maa n mu ekun iyawo wa. ti igbeyawo ba ti ku ola ni omobinrin yoo maa sun ekun iyawo. Ekun iyawo maa n kun fun ibeere imoran, oriki orile, oro iwuri, iwure, awada, eyi si maa n la be lo.

No comments :

Post a Comment