Dishing Out Yoruba The Best Way (warning: do not translate with software to avoid misinterpretation)

Iro Ohun ati Ami Ohun (Yoruba Tonal Sounds and Signs)

No comments :

Iro Ohun ni ilana igbesoke gbesodo ohun eniyan ti o n se ifo. A le pin iro ohun si meji ninu ede Yoruba; iro ohun geere (iro ohun oke, iro ohun isale ati iro ohun aarin) ati iro ohun eleyoo (iro ohun eleyooroke ati iro ohun eleyoorodo).Apeere:
Iro ohun oke ni a maa n lo ami ohun oke fun (/).
Iro ohun isale ni a maa n lo ami ohun isale fun (\).
Iro ohun aarin ni a maa n lo ami ohun aarin fun (-).
Iro ohun eleyooroke ni a maa n lo ami ohun eleyooroke (\/).
Iro ohun eleyoorodo ni a maa n lo ami ohun eleyoorodo (/\).
Iro ohun oke = Fún
Iro ohun isale = Gbà
Iro ohun aarin = Se
Iro ohun eleyooroke = Yìí
Iro ohun eleyoorodo = Náà

Ami ohun ni ami ti a maa n lo lati fi iyato iro ohun han nigba ti a ba n se iro ninu ede Yoruba. A ti fi ogun menu ba won ninu alaye ti a ti se saaju.

O se pataki fun akekoo la ranti wi pe a kii fi ami ohun si ori silebu inu oro ti iro ohun re je iro ohun aarin (eyi ti a mo si "re"). Akiyesi miiran ni pe, ami ohun oke ati ami ohun isale maa n fara han lori awon iro konsonanti aranmu asesilebu.

No comments :

Post a Comment